Guidance

Notice of rights and entitlements Yoruba (PACE Code H) (accessible version)

Updated 23 January 2020

Òfin Ìwà Kòkọkú 2000

Rántí àwọn ẹ̀ tọ́ rẹ nígbàtí o wà ní àtìmọ́ lé

Àwọn ẹ̀ tọ́ nínú Àkíyèsí yìí ni a fọ́wọ́sọ̀yà fún ọ lábẹ́ òfin Ilẹ̀ England àti Wales ó sì faramọ́ Òfin Ìlànà EU 2012/13 lórí ẹ̀ tọ́ sí àlàyé lórí àwọn ìlànà iṣẹ́ ọ̀daràn.

Àwọn ẹ̀ tọ́ rẹ ní àgọ́ ọlọ́pàá ní a sọ níṣókí lójú-ewé yìí.

Ọ̀pọ̀ àlàyé wà ní àwọn àlàfo ìlà 1 sí 11 ní àwọn ójú-ewé tókàn.

Ẹ̀kúnrẹ́ rẹ́ àlàyé wà nínú Òfin Ìhùwàsí H ti ọlọ́pàá.

  1. Sọ fún ọlọ́pàá tí o bá fẹ́ kí agbẹjọ́ rò kan ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbàtí o wà ní àgọ́ ọlọ́pàá. Ọ̀fẹ́ ni èyí.

  2. Sọ fún ọlọ́pàá tí o bá fẹ́ kí a sọ fún ẹnìkan ibi tí o wà. Ọ̀fẹ́ ni èyí.

  3. Sọ fún ọlọ́pàá tí o bá fẹ́ wo àwọn òfin wọn - a ń pè wọ́n ní Òfin Ìhùwàsí.

  4. Sọ fún ọlọ́pàá tí o bá nílò ìrànlọ́wọ́ ìtọ́ jú ìlera. Sọ fún ọlọ́pàá tí o bá ń ṣàìsàn tàbí o ní ìpalára. Ọ̀fẹ́ ni ìrànlọ́wọ́ ìlera.

  5. Tí a bá bèrè lọ́wọ́ rẹ nípa ìkópa àfurasí rẹ nínú ìṣẹ̀ lẹ̀ náà, ìgbáradì tàbí ṣíṣe kóríyá fún ìṣe kòkọkú, o kò ní láti sọ ohunkóhun. Ṣùgbọ́n ó le kóbá ààbò rẹ tí o kò bá sọ̀ rọ̀ nígbàtí a bá bèrè ohùnkan èyítí o wá fọkàntẹ̀ tóbáyá ní ilé-ẹjọ́ . Ohunkóhun tí o bá sọ ni a le lò bíi ẹ̀ rí.

  6. Ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ sọ fún ọ nípa irú ìkópa afurasí rẹ nínú ìṣẹ̀ lẹ̀ náà, ìgbáradì tàbí ṣíṣe kóríyá fún ìṣe kòkọkú àti ìdí tí a fi mú ọ tí a sì tì ọ́ mọ́ lé.

  7. Ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìwọ tàbí agbẹjọ́ rò rẹ rí àwọn ohun àkásílẹ̀ àti ohun àkọsílẹ̀ nípa ìdí tí a fí mú ọ tí a sì tì ọ́ mọ́ lé àti nípa àsìkò rẹ ní àgọ́ ọlọ́pàá.

  8. Tí o bá nílò ògbùfọ̀ kan, ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ pèsè ìkan fún ọ. O tún le ní àwọn ohun àkọsílẹ̀ kan nílẹ̀ tí a ti túmọ̀ . Ọ̀fẹ́ ni èyí

  9. Sọ fún ọlọ́pàá tí o kò bá jẹ́ ọmọ ìlú Biritiṣi tí o sì fẹ́ kàn sí ilé-iṣẹ́ tàbí aṣojú orílẹ̀ - èdè rẹ tàbí o fẹ́ kí a sọ fún wọn wípé o wà ní àtìmọ́ lé. Ọ̀fẹ́ ni èyí.

  10. Ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ sọ fún ọ ìgbà tí ó pẹ́ jù tí o fi le wà ní àtìmọ́ lé.

  11. Tí a bá fi ẹ̀sùn kàn ọ́ tí a sì gbé ọ lọ sí ilé-ẹjọ́ , ìwọ tabí agbẹjọ́ rò rẹ yóò ní ẹ̀ tọ́ láti rí ẹ̀ rí ìjẹ́ jọ́ ṣáájú gbígbọ́ ilé-ẹjọ́ .

Tí èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ tọ́ wọ̀nyí kò bá dá ọ lójú, sọ fún ọ̀gá ọlọ́pàá ibi àtìmọ́ lé

Wo àwọn ojú-ewé náà lẹ́yìn ìsọníṣókí fún ọ̀pọ̀ àlàyé nípa bí àwọn ọlọ́pàá ti gbọ́dọ̀ ṣe ọ́ tàbí tọ́ jú rẹ

Ẹ̀yà yìí ti Àkíyèsí Àwọn Ẹ̀tọ́ àti Àjẹmọ́nú nípa láti ojo kanle logun, osun kejo odun 2019

Jọ̀wọ́ tọ́ jú àlàyé yìí kí o sì kàá ní kété. Yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpínnu nígbàtí o wà ní àgọ́ ọlọ́pàá.

1. Gbígba agbẹjọ́rò láti ràn ọ́ lọ́wọ́

  • Agbẹjọ́ rò kan le ràn ọ́ lọ́wọ́ kó sì gbà ọ́ nímọ̀ ràn nípa òfin náà.
  • Bíbèrè láti bá agbẹjọ́ rò sọ̀ rọ̀ kò jẹ́ kò farahàn bíi wípé o ti ṣe ohun tí kò dára.
  • Ọ̀gá àgọ́ ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ bèrè lọ́wọ́ rẹ tí o bá fẹ́ ìmọ̀ ràn òfin. Ọ̀fẹ́ ni èyí.
  • Ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ jẹ́ kí o bá agbẹjọ́ rò kan sọ̀ rọ̀ nígbàkugbà, ní ojú ọjọ́ tàbí àṣálẹ́ , nígbàtí o bá wà ní àgọ́ ọlọ́pàá.
  • Tí o bá bèrè fún ìmọ̀ ràn òfin, a kò fi àyè gba ọlọ́pàá láàyè láti bi ọ́ ní àwọn ìbéèrè títí wàá fi ní ààyè láti bá agbẹjọ́ rò rẹ sọ̀ rọ̀ . Nígbàtí ọlọ́pàá bá bí ọ́ ní àwọn ìbéèrè o le bèrè fún agbẹjọ́ rò kan láti wà nínú yàrá pẹ̀ lú rẹ.
  • Tí o bá sọ fún ọlọ́pàá wípé o kò fẹ́ ìmọ̀ ràn òfin ṣùgbọ́n tí o wá yí ọkàn rẹ padà, sọ fún ọ̀gá àgọ́ ọlọ́pàá tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kàn sí agbẹjọ́ rò kan.
  • Tí agbẹjọ́ rò kan kò bá farahàn tàbí kàn sí ọ ní àgọ́ ọlọ́pàá, tàbí o nílò láti tún bá agbẹjọ́ rò sọ̀ rọ̀ lẹ́ẹ̀kan síi, sọ fún ọlọ́pàá láti tún bá wọn sọ̀ rọ̀ lẹ́ẹ̀kan síi.
  • O le bèrè láti bá agbẹjọ́ rò kan tí o mọ̀ sọ̀ rọ̀ , o kò sì ní láti sanwó tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ agbẹjọ́ rò ọ̀ fẹ́ . Tí o kò bá mọ agbẹjọ́ rò kankan tàbí a kò le kàn sí agbẹjọ́ rò tí o mọ̀ , o le bá agbẹjọ́ rò tó wà lẹ́nu iṣẹ́ sọ̀ rọ̀ . Ọ̀fẹ́ ni.
  • Agbẹjọ́ rò tó wà lẹ́nu iṣẹ́ kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀ lú ọlọ́pàá.

Láti ṣètò fún ìmọ̀ràn òfin lọ́fẹ̀ẹ́:

  • Ọlọ́pàá yóò kàn sí Ibi Ìpè Agbẹjọ́ rò Olùjẹ́ jọ́ (DSCC). DSCC yóò sì ṣètò láti fún ọ ní ìmọ̀ ràn òfin láti agbẹjọ́ rò tí o bèrè fún tàbí Agbẹjọ́ rò Ẹnu Iṣẹ́ .
  • DSCC jẹ́ iṣẹ́ tó dá wà èyítí ń ṣètò fún ìmọ̀ ràn òfin lọ́ fẹ̀ẹ́ kò sì ni ohunkóhun ṣe pẹ̀ lú ọlọ́pàá.

Tí o bá fẹ́ sanwó fún ìmọ̀ràn òfin fúrarẹ:

  • Nínú gbogbo ẹ̀sùn o le sanwó fún ìmọ̀ ràn òfin tí o bá fẹ́ .
  • DSCC yóò kàn sí agbẹjọ́ rò tìrẹ lórúkọ rẹ.
  • O ní ẹ̀ tọ́ láti bá agbẹjọ́ rò rẹ tí o yàn sọ̀ rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀ lórí ẹ̀ rọ ìbánisọ̀ rọ̀ tàbí wọ́n le pinnu láti wá rí ọ ní àgọ́ ọlọ́pàá.
  • Tí a kò bá le kàn sí agbẹjọ́ rò tí o fẹ́ , ọlọ́pàá sì le pe DSCC láti ṣètò fún ìmọ̀ ràn òfin lọ́ fẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ Agbẹjọ́ rò Ẹnu Iṣẹ́ .

2. Sísọ fún ẹnìkan wípé o wà ní àgọ́ ọlọ́pàá

  • O le sọ fún ọlọ́pàá láti bá ẹnìkan sọ̀ rọ̀ tó ní láti mọ̀ wípé o wà ní àgọ́ ọlọ́pàá. Ọ̀fẹ́ ni èyí.
  • Wọn yóò kàn sí ẹnìkan fún ọ ní kíá.

3. Wíwo Àwọn Òfin Ìhùwàsí

  • Àwọn òfin ìhùwàsí jẹ́ àwọn ìlànà tí yóò sọ fún ọ ohun tí ọlọ́pàá le ṣe tàbí tí wọn kò le ṣe nígbàtí o wà ní àgọ́ ọlọ́pàá. Ó pẹ̀ lú ẹ̀kúnrẹ́ rẹ́ àlàyé àwọ́n ẹ̀ tọ́ tí a sọ ní ṣókí nínú Àkíyèsí yìí.
  • Ọlọ́pàá yóò jẹ́ kí o ka Àwọn Òfin Ìhùwàsí náà, ṣùgbọ́n o kò le ṣe èyí tí àwọn ọlọ́pàá kò bá tí mọ̀ bóyá o rúfin tàbí bẹ́ẹ̀kọ́ .
  • Tí o bá fẹ́ ka Àwọn Òfin Ìhùwàsí náà, sọ fún Ọ̀gá Àgọ́ Ọlọ́pàá.

4. Gbígba ìrànlọ́wọ́ ìtọ́ jú ìlera tí ara rẹ kò bá yá tàbí o ní ìpalára

  • Sọ fún ọlọ́pàá tí o bá ń ṣe àìsàn tàbí o nílò ògùn tàbí o ní ìpalára. Wọn yóò pe oníṣègùn òyìnbó tàbí olùtọ́ jú tàbí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ iṣẹ́ ìlera míràn ọ̀ fẹ́ sì ni èyí.
  • A le gbà ọ́ láàyè láti lo ògùn tìrẹ, ṣùgbọ́n ọlọ́pàá kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò rẹ̀ . Olùtọ́ jú yòó kọ́kọ́ rí ọ, ṣùgbọ́n ọlọ́pàá yóò ránṣẹ́ sí oníṣègùn òyìnbó kan tí o bá nílò rẹ̀ . O le bèrè láti rí oníṣègùn òyìnbó míràn, ṣùgbọ́n o le ní láti sanwó fún èyí.

5. Ẹ̀tọ́ láti dákẹ́ jẹ́

Tí a bá bèrè lọ́wọ́ rẹ nípa ìkópa afurasí rẹ nínú ìṣẹ̀ lẹ̀ náà, ìgbáradì tàbí ṣíṣe kóríyá fún àwọn ìṣe kòkọkú, o kò ní láti sọ ohunkóhun.

Ṣùgbọ́n, ó le nípa lórí ìjẹ́ jọ́ rẹ tí o kò bá sọ̀ rọ̀ nígbàtí a bá bèrè lọ́wọ́ rẹ ohùnkan tí o le gbẹ́kẹ̀ lé tóbáyá ní ilé-ẹjọ́ .

Ohunkóhun tí o bá sọ ni a le fi sílẹ̀ nínú ẹ̀ rí.

6. Mímọ̀ nípa ìdí tí a fi mú ọ tí a sì tì ọ́ mọ́ lé

  • Ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ pèsè àlàyé fún ọ kí o le lóye ìdí tí a fi mú ọ tí a sì furasí wípé o kópa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ìgbáradì tàbí ṣíṣe kóríyá fún ìwà kòkọkú.
  • Ní àgọ́ ọlọ́pàá, ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ sọ fún ọ ìdí tí wọ́n fi gbàgbọ́ wípé wọ́n gbọ́dọ̀ tí ọ mọ́ lé.
  • Kí wọ́n tó bèrè ohunkóhun lọ́wọ́ rẹ nípa ìkópa afurasí rẹ nínú ìwà kòkọkú, ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ fún ọ tàbí agbẹjọ́ rò rẹ ní ọ̀pọ̀ àlàyé nípa ohun tí wọ́n rò wípé o ti ṣe kí o le yanjú ara rẹ làì dènà ìtọpinpin ọlọ́pàá.
  • Èyí kan èyíkéyìí ìwà ọ̀daràn tí ọlọ́pàá fi fura sí ọ.

7. Rírí àwọn ohun àkásílẹ̀ àti àkọsílẹ̀ nípa mímú àti àtìmọ́ lé rẹ

  • Nígbàtí a bá tí ọ́ mọ́ lé ní àgọ́ ọlọ́pàá, ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ :
    • Ṣàkọsílẹ̀ ohun àkásílẹ̀ ìwọlé rẹ, ìdí ati èrèdí tí a fi mú ọ àti ìdí tí a fi gbàgbọ́ wípé a gbọ́dọ̀ tí ọ́ mọ́ lé.
    • Jẹ́ kí ìwọ àti agbẹjọ́ rò rẹ wo àwọn ohun àkásílẹ̀ wọ̀nyí. Ọ̀gá àgọ́ ọlọ́pàá yóò ṣètò èyí.
  • Ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ fún ìwọ tàbí agbẹjọ́ rò rẹ láàyè sí àwọn ohun àkọsílẹ̀ rẹ àti àwọn ohun èlò tó ṣe pàtàkì sí ìpèníjà mímú ati àtìmọ́ lé rẹ tó bá òfin mu.

8. Gbígba ògbùfọ̀ àti àwọn ìtúmọ̀ èdè ti àwọn ohun àkọsílẹ̀ kan ní pàtó láti ràn ọ́ lọ́wọ́

  • Tí o kò bá sọ tàbí lóye èdè Gẹ̀ẹ́sì, ọlọ́pàá yóò ṣètò fún ẹnìkan tí ń sọ èdè rẹ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ . Ọ̀fẹ́ ni èyí.
  • Tí o bá jẹ́ odi tàbí o kò le sọ̀ rọ̀ dáradára, ọlọ́pàá yóò ṣètò fún ògbùfọ̀ Èdè Gẹ̀ẹ́sì Odi Ti Biritiṣi láti ràn ọ́ lọ́wọ́ . Ọ̀fẹ́ ni èyí.
  • Tí o kò bá sọ tàbí lóye èdè Gẹ̀ẹ́sì, ọlọ́pàá yóò gba ògbùfọ̀ kan láti sọ fún ọ ìdí tí wọ́n fi ń tì ọ́ mọ́ lé. A gbọ́dọ̀ ṣe èyí nígbàkúgbà tí a bá ṣe ìpinnu láti fi ọ́ pamọ́ .
  • Lẹ́yìn ìpinnu kọ̀ọ̀kan láti fi ọ́ pamọ́ àti lẹ́yìn tí a bá ti fi èyíkéyìí ẹ̀sùn kàn ọ́ ọlọ́pàá tún gbọ́dọ̀ fún ọ ní ohun àkásílẹ̀ kan ní èdè tìrẹ ìdí tí a fi ń tì ọ́ mọ́ lé àti eyíkéyìí ẹ̀sùn tí a fi kàn ọ́ , àyàfi tí àwọn ìdí pàtàkì bá wà láti má ṣe bẹ́ẹ̀ . Ìwọ̀nyí ni:
    • Tí o bá pinnu wípé o kò nílo ohun àkásílẹ̀ láti gba ara rẹ sílẹ̀ nítorí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ yé ọ dáradára àti àwọn àbájáde àìní ohun àkásílẹ̀ tí o sì ti ní ànfàní láti bèrè fún ìrànlọ́wọ́ lọ́wọ́ agbẹjọ́ rò kan. O tún gbọ́dọ̀ sọ ìyọ̀ndà rẹ nípa kíkọsílẹ̀ .
    • Tí níní ìtúmọ̀ èdè àfẹnusọ tàbí ìsọníṣókí nípasẹ̀ ògbùfọ̀ kan dípò ìtúmọ̀ èdè tí a kọsílẹ̀ yóò bá tó fún ọ láti gba ara rẹ sílẹ̀àti láti lóye ní ẹ̀kúnrẹ́ rẹ́ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ . Ọ̀gá àgọ́ tún gbọ́dọ̀ fi àṣẹ sí èyí.
  • Nígbàtí ọlọ́pàá bá bèrè àwọn ìbèrè lọ́wọ́ rẹ tí wọn kò sì ká ohùn rẹ sílẹ̀ , ògbùfọ̀ yóò ṣe ìkásílẹ̀ àwọn ìbèrè náà àti awọn ìdáhùn rẹ ní èdè tìrẹ. Wàá le ṣàyẹ̀wò èyí kí o tó le buwọ́ lùú bíi ìkásílẹ̀ tó péye.
  • Tí o bá fẹ́ kọ ohunkóhun sílẹ̀ fún ọlọ́pàá, ògbùfọ̀ náà yóò ṣe ẹ̀dà gbólóhùn náà ní èdè tìrẹ fún ọ láti ṣàyẹ̀wò kí o sì buwọ́ lùú wípé ó péye.
  • O tún ní ẹ̀ tọ́ sí ìtúmọ̀ ti Àkíyèsí yìí. Tí kò bá sí ìtúmọ̀ èdè nílẹ̀ , a gbọ́dọ̀ ṣàlàyé náà fún ọ nípasẹ̀ ògbùfọ̀ kan kí a sì pèsè ìtúmọ̀ rẹ̀ fún ọ láìsí ìdádúró.

9. Kíkànsí ilé-iṣẹ́ tàbí aṣojú orílẹ̀-èdè rẹ

Tí o kò bá jẹ́ ọmọ orílẹ̀ -èdè Biritiṣi, o le sọ fún ọlọ́pàá wípé o fẹ́ kàn sí Ọ̀gá Àgbà, Ilé-iṣẹ́ tàbí Aṣojú orílẹ̀ -èdè rẹ láti sọ fún wọn ibi tí o wà àti ìdí tí o fi wà ní àgọ́ ọlọ́pàá. Wọ́n tún le bẹ̀ ọ́ wò ní ìkọ̀kọ̀ tàbí ṣètò fún agbẹjọ́ rò kan láti rí ọ.

10. Fún ìgbà wo ni a fi le tì ọ́ mọ́ lé

  • A le tì ọ́ mọ́ lé fún ju wákàtí 48 lọ láì gbé ọ lọ sí ilé-ẹjọ́ tí ilé-ẹjọ́ kan bá gba ọlọ́pàá láàyè fún ọ̀pọ̀ àkókò láti tì ọ́ mọ́ lé. Àwọn ilé-ẹjọ́ ní agbára láti sún àkókò ìtìmọ́ lé náà síwájú láì gbé ọ lọ sí ilé-ẹjọ́ fún bíi ọjọ́ 14 láti ìgbà tí a mú ọ.
  • Nígbà gbogbo ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò ẹ̀sùn rẹ bí a bá sì tún ní láti tì ọ́ mọ́ lé. Èyí ni a ń pè ní àtúnyẹ̀wò. Àyàfi tí ara rẹ kò bá yá, o ní ẹ̀ tọ́ láti sọ̀ rọ̀ nípa ìpinnu yìí. Agbẹjọ́ rò rẹ tún ní ẹ̀ tọ́ láti sọ̀ rọ̀ nípa ìpinnu yìí lórúkọ rẹ.
  • Tí ọ̀gá àtúnyẹ̀wò kò bá fi ọ sílẹ̀ , wọ́n gbọ́dọ̀ sọ ìdí fún ọ kí a sì ká ìdí náà sílẹ̀ sínú ohun ikásílẹ̀ rẹ.
  • Tí àtìmọ́ llé rẹ kò bá ṣe pàtàkì mọ́ a gbọ́dọ̀ tú ọ sílẹ̀ .
  • Nígbàtí ọlọ́pàá bá sọ fún ilé-ẹjọ́ láti fa àtìmọ́ lé rẹ gùn:
    • A gbọ́dọ̀ fún ọ ní àkíyèsí tí a kọsílẹ̀ èyítí ń wí fún ọ nígbàtí ìgbẹ́ jọ́ náà yóò wáyé àti èrèdí fún bíbèrè láti fa àtìmọ́ lé rẹ gùn.
    • A gbọ́dọ̀ mú ọ wá sí ilé-ẹjọ́ fún gbígbọ́ náà àyàfi tí a bá ṣàgbékalẹ̀ ìsopọ̀ ẹ̀ rọ amóhùnmáwòrán kan kí o le rí kí o sì gbọ́ àwọn ènìyàn nínú ilé-ẹjọ́ kí wọ́n sí le rí ọ àti láti gbọ́ ọ pẹ̀ lú.
    • O ní ẹ̀ tọ́ láti ní agbẹjọ́ rò kan pẹ̀ lú rẹ ní ilé-ẹjọ́ .
    • A le gba ọlọ́pàá láàyè láti fí ọ sí àtìmọ́ lé tí ilé-ẹjọ́ bá gbàgbọ́ wípé ó ṣe pàtàkì àti wípé ọlọ́pàá ń ṣe àyẹ̀wò ẹjọ́ rẹ dáradára àti láìsí ìdènà tí kò yẹ.
  • Tí ọlọ́pàá bá ní ọ̀pọ̀ ẹ̀ rí láti fi rán ọ sí ilé-ẹjọ́ , a le fẹsùn kàn ọ́ ní àgọ́ ọlọ́pàá tàbí nípa ìwé ìfiránṣẹ́ , láti farahàn ní ilé-ẹjọ́ fún àyẹ̀wò.

Àwọn àtúnyẹ̀wò ati fífa àtìmọ́ lé gùn

  • Àwọn ìṣẹ̀ lẹ̀ kan le wa tí a fi le tì ọ́ mọ́ lé fún ìgbà tó ju wákàtí 48 lọ lẹ́yìn tí a mú ọ. Ní àwọn ìṣẹ̀ lẹ̀ wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ fún ọ ní nkan wọ̀nyí:
    • Ìwé àkọsílẹ̀ wípé a ti ṣe ìwé ìbèrè láti fa àtìmọ́ lé rẹ gùn;
    • Àkókò tí a ṣe ìwé ìbèrè náà;
    • Àkókò tí a ó gbọ́ ìwé ìbèrè náà ní ilé-ẹjọ́ àti
    • (Àwọn) ìdí tí a fi ń bèrè fún àtìmọ́ lé tó pẹ́ .

A tún gbọ́dọ̀ pèsè àkíyèsí kan fún ọ (àti aṣojú iṣẹ́ òfin rẹ) ìgbàkúgbà tí a bá ṣe ìwé ìbèrè láti fàgùn tàbí tún fa àtìmọ́ lẹ̀ rẹ gùn síwájú síi.

11. Ìráyèsí ẹ̀rí náà tí ẹjọ́ rẹ bá lọ sí Ilé-ẹjọ́

Tí a bá fi ẹ̀sùn kan kàn ọ́ , ìwọ tàbí agbẹjọ́ rò rẹ ni a gbọ́dọ̀ gbà láàyè láti rí ẹ̀ rí náà tó lòdì sí ọ àti pẹ̀ lú ẹ̀ rí tó le ran ìgbàsílẹ̀ rẹ lọ́wọ́ . A gbọ́dọ̀ ṣe èyí kí ìjẹ́ jọ́ rẹ tó bẹ̀ rẹ̀ . Ọlọ́pàá àti Crown Prosecution Service gbọ́dọ̀ ṣètò fún èyí kí wọ́n sì pèsè ìráyèsí àwọn ìwé àkọsílẹ̀ náà àti ohun èlò tó ṣe pàtàkì.

Àwọn ohun míràn tí o ní láti mọ̀ nípa wíwà ní àgọ́ ọlọ́pàá

Bí a ti gbọ́dọ̀ ṣe ọ́ kí a sì tọ́ jú rẹ

Àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí ń sọ fún ọ nípa ohun tí o le retí nígbàtí a bá fi ọ pamọ́ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Láti mọ̀ síwájú síi, bèrè láti rí Àwọn Òfin Ìhùwàsí. Wọ́n pẹ̀ lú àkójọ ibi tí o ti le rí àlàyé síwájú síi nípa ìkọ̀kan nínú àwọn nkan wọ̀nyí. Bèrè lọ́wọ́ ọ̀gá ọlọ́pàá tí o bá ní èyíkéyìí ìbéèrè.

Àwọn ènìyàn tó nílò ìrànlọ́wọ́

  • Tí ọjọ́ orí rẹ kò bá tó 18 tàbí o jẹ́ abarapá, fún àpẹrẹ tí o bá ní ìṣòro ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí àwọn ìṣòro iṣẹ́ ọpọlọ, fún ìdí èyí o ní ẹ̀ tọ́ kan láti ní ẹnìkan pẹ̀ lú rẹ nígbàtí àwọn ọlọ́pàá bá ń ṣe àwọn nkan. Ẹni yìí ni a ń pè ní “àgbàlagbà tó péye” a ó sì fún wọn ní ẹ̀dà kan ti Àkíyèsí yìí.
  • Àgbàlagbà rẹ tó péye yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ń ṣẹlẹ̀ yóò sì máa ṣe ìfẹ́ inú rẹ. Ó gbọ́dọ̀ wà pẹ̀ lú rẹ nígbàtí ọlọ́pàá bá sọ fún ọ nípa àwọn ẹ̀ tọ́ rẹ tí wọ́n sì sọ fún ọ ìdí tí a fi ń tì ọ́ mọ́ lé. Ó tún gbọ́dọ̀ wà pẹ̀ lú rẹ nígbàtí ọlọ́pàá bá ka ìkìlọ̀ fún ọ.
  • Àgbàlagbà rẹ tó péye tún le bèrè fún agbẹjọ́ rò kan lórúkọ rẹ.
  • O le bá agbẹjọ́ rò rẹ sọ̀ rọ̀ láìsí àgbàlagbà rẹ tó péye nínú yàrá tí o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ .
  • Ọlọ́pàá tún le fẹ́ ṣe ọ̀kan nínú àwọn nkan tí a kọ sísàlẹ̀ nígbàtí o wà ní àgọ́ ọlọ́pàá. Àyàfi tí àwọn ìdí pàtàkì kan bá wà, àgbàlagbà rẹ tó péye gbọ́dọ̀ wà pẹ̀ lú rẹ fún gbogbo àkókò náà tí ọlọ́pàá bá ṣe ìkankan nínú ìwọ̀nyí:
    • Fọ̀ rọ̀ wá ọ lẹ́nu wò tàbí bèrè lọ́wọ́ rẹ láti buwọ́ lu gbólóhùn àkọsílẹ̀ tàbí àwọn àkọsílẹ̀ ọlọ́pàá.
    • Bọ́ ju àwọn aṣọ òde rẹ lọ láti yẹ̀ ọ́ wò.
    • Gba ilà ìka-ọwọ́ rẹ, fọ́ tò tàbí DNA kan tàbí àpèjúwe míràn.
    • Ṣe ohunkóhun tó níṣe pẹ̀ lú ìlànà ìdánimọ̀ ajẹ́ rìí.
  • A gbọ́dọ̀ fún àgbàlagbà rẹ tó péye láàyè láti wà níbẹ̀ lójúkoju tàbí lórí ẹ̀ rọ ìbánisọ̀ rọ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbàtí ọlọ́pàá bá ṣàtúnyẹ̀wò ẹ̀sùn rẹ láti ríi bóyá kí a tì ọ́ mọ́ lé síi.
  • Tí àgbàlagbà rẹ tó péye bá wà nílẹ̀ , wọ́n gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀nígbàtí ọlọ́pàá bá fi èyíkéyìí ẹ̀sùn kàn ọ́ .

Gbígba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé ti àkókò rẹ ní àgọ́ ọlọ́pàá

  • Ohun gbogbo tó ṣẹlẹ̀ sí ọ nígbàtí o wà ní àgọ́ ọlọ́pàá ni a kásílẹ̀ . Èyí ni a ń pè ní Ohun Ìkásílẹ̀ Àtìmọ́ lé.
  • Nígbàtí o bá kúrò ní àgọ́ ọlọ́pàá, ìwọ, agbẹjọ́rò rẹ tàbí àgbàlagbà rẹ tó péye le bèrè fún ẹ̀dà Ohun Ìkásílẹ̀ Àtìmọ́ lé. Ọlọ́pàá ní láti fún ọ ní ẹ̀dà kan ti Ohun Ìkásílẹ̀ Àtìmọ́ lé ní kété tí wọ́n bá ti le ṣeé.
  • le bèrè lọ́wọ́ ọlọ́pàá ẹ̀dà Ohun Ìkásílẹ̀ Àtìmọ́ lé rẹ èyí tí ó tó oṣù 12 lẹ́yìn tí o fi àgọ́ ọlọ́pàá sílẹ̀ .

Wíwà ní àrọ́wọ́tó

  • Gẹ́gẹ́ bíi bíbá agbẹjọ́ rò kan sọ̀ rọ̀ àti sísọ fún ènìyàn kan nípa àtìmọ́ lé rẹ a ó máa gbà ọ́ láàyè láti pe ìpè kan.
  • Bèrè lọ́wọ́ ọlọ́pàá tí o bá fẹ́ pe ìpè orí ago.
  • O tún le bèrè fún kálàmù àti tákàndá.
  • O tún le ní àwọn àlejò ṣùgbọ́n ọ̀gá ọlọ́pàá àtìmọ́ lé le kọ̀ láti gba èyí láàyè.

Ẹ̀wọ̀n Rẹ

  • Tó bá ṣeéṣe a gbọ́dọ̀ fi ọ́ sí inú ẹ̀wọ̀n láti dá wà.
  • Ó gbọ́dọ̀ mọ́ , mú oru kó sì ní iná.
  • Ibùsùn rẹ gbọ́dọ̀ mọ́ kí a sì tẹ́ẹ dáradára.
  • A gbọ́dọ̀ gbà ọ́ láàyè láti lo ilé ìgbọ̀nsẹ̀ kí o sì le fọwọ́ .

Awon ohun ohun elo ti ara – ilera, imototo ati itoju

  • Won ni lati beere lowo re ti o ba fe ba wa soro ni ibi koko pelu okan ninu awon osise wa nipa ohun to jomo eto ara ti o ni se pelu ilera, imototo ati re ti o le ni ipa tabi ti o jo mo e nigba ti o ba wa ni ogba atimole.
  • Olopa yoo se eto lati pese ohun ti a lero pe o nilo. Ti o ba fe, eni ti o ba e soro le je eya abo tabi ako bi tire.
  • Ti o ba je obirin ti o ti pe omo odun (meji dilogun) tabi ti o ju be lo, a ni lati beere lowo re ti o ba fe tabi ti o ba ma ni lo awon ohun ti a lo lati fi se nkan osu ni igba ti o ba wa ni atimole ati wi pe a ni lati so fun e pe:
    • awonohun elo ni a o pese fun o ni ofe;
    • awon ohun ti o ba nlo ti o ba tan, a setan lati pese omiran fun o; ati pe
    • awon ohun elo yi ni awon ebi re tabi ore re le pese fun o ni apo ara won ti awon osise abojuto ba fara mo.
  • Ti o ba je omobirin ti ko ti pe omo odun (meji dilogun), awon osise abojuto ma seto wi pe obirin ti o wa ni ago olopa wa lati toju re ati pe yo beere ti o ba fe ohun elo ati lati fi se nkan osu.

Àwọn aṣọ

Tí a bá gba àwọn aṣọ rẹ lọ́wọ́ rẹ, ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ pèsè irúfẹ́ aṣọ míràn fún ọ.

Oúnjẹ àti ohun mímú

A gbadọ̀ fún ọ ní oúnjẹ ní ìgbà mẹ́ ta lójúmọ́ pẹ̀ lú ohun mímu. O tún le ní àwọn ohun mímu láàrín àkókò oúnjẹ.

Eré ìdáráyá

Tí ó bá ṣeéṣe a gbọ́dọ̀ gbá ọ́ láàyè láti jáde láti le gba atẹ́gùn ní ojojúmọ́ .

Nígbàtí ọlọ́pàá bí fi ọ̀rọ̀ wá ọ lẹ́nu wò

  • Yàrá náà gbọ́dọ̀ mọ́ , mú oru kó sì ní iná.
  • kò ní láti dúró.
  • Àwọn Ọ̀gá Ọlọ́pàá gbọ́dọ̀ sọ orúkọ àti ipò wọn fún ọ.
  • gbọ́dọ̀ ní àkókò ìjáde fún ìgbà oúnjẹ àti àkókò ìjáde fún ohun mímu lẹ́yìn bíi wákàtí méjì.
  • A gbọ́dọ̀ gbà ọ́ láàyè fún ìsinmi bíi wákàtí 8 ó kéré jù láàrín wákàtí 24 tí o fi wà ní àtìmọ́ lé.

Àwọn Ohun Ìní Ẹ̀sìn

Sọ fún ọlọ́pàá tí o bá nílò ohunkóhun láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ ẹ̀sìn rẹ nígbàtí o wà ní àgọ́ ọlọ́pàá. Wọ́n le pèsè àwọn ìwé ẹ̀sìn àti nkan míràn, bí o ti ṣe nílò wọ́n.

Àwọ́n ìgbà tí àwọn òfin tí a máa ń lò le yàtọ̀

Gbígba agbẹjọ́rò láti ràn ọ́ lọ́wọ́

Àwọn ìgbà míràn máa ń wà tí ọlọ́pàá ní láti bèrè àwọn ìbéèrè kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ rẹ ní kánjúkánjú kí o tó le bá agbẹjọ́ rò kan sọ̀ rọ̀ . Àlàyé nípa èyí ni a kọ sínú Àwọn Òfin Ìhùwàsí. Èyí ṣàtúpalẹ̀ ohun tí ọlọ́pàá le ṣe àti ohun tí wọn kò le ṣe nígbàtí o wà ní àgọ́ ọlọ́pàá. Tí o bá fẹ́ wo ẹ̀kúnrẹ́ rẹ́ àlàyé, wọ́n wà ní àlàfo ìlà 6.7 ti Òfin H ti Àwọn Òfin Ìhùwàsí.

Ìgbà kan wà tí ọlọ́pàá kò ní jẹ́ kí o bá agbẹjọ́ rò náà tí o ti yàn sọ̀ rọ̀ . Tí èyí bá ṣẹlẹ̀ a gbọ́dọ̀ gbà ọ́ láàyè láti yan agbẹjọ́ rò míràn. Tí o bá fẹ́ wo ẹ̀kúnrẹ́ rẹ́ àlàyé, wọ́n wà nínú Ìtọ́ka B ti Òfin H ti Àwọn Òfin Ìhùwàsí.

Ìgbà kan wà tí ọlọ́pàá kò ní jẹ́ kí o bá agbẹjọ́ rò rẹ sọ̀ rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀ . Èyí jẹ́ àkókò tí ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá bá ṣòfin fún ọ̀ tẹlẹ̀múyẹ́ tó wọ aṣọ láti wà níbẹ̀ . Tí o bá fẹ́ wo ẹ̀kúnrẹ́ rẹ́ àlàyé, wọ́n wà ní àlàfo ìlà 6.5 ti Òfin H ti Àwọn Òfin Ìhùwàsí.

Sísọ fún ẹnìkan wípé o wà ní àgọ́ ọlọ́pàá

Àwọn ìgbà míràn máa ń wà tí ọlọ́pàá kò ní gbà ọ́ láàyè láti bá ẹnikẹ́ni sọ̀ rọ̀ . Àlàyé nípa èyí ni a kọ sínú Àwọn Òfin Ìhùwàsí. Tí o bá fẹ́ wo ẹ̀kúnrẹ́ rẹ́ àlàyé, wọ́n wà nínú Ìtọ́ka B ti Òfin H ti Àwọn Òfin Ìhùwàsí.

Àwọn Àlejò Àtìmọ́ lé Olómìnira

Àwọn ará àdúgbò kan wà tí a ń gbà láàyè láti wọ àgọ́ ọlọ́pàá láì ṣọ fún ẹnikẹ́ni tẹ́ lẹ̀ . Àwọn ni a mọ̀ sí àwọn àlejò àtìmọ́ lé olómìnirà wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ lọ́ fẹ̀ẹ́ láti ṣàrídájú wípé àwọn tí a tìmọ́ lé ni a ń tọ́ jú dáradára wọ́n sì ní ààyè sí àwọn ẹ̀ tọ́ wọn.

O kò ní ẹ̀ tọ́ láti rí àlejò àtìmọ́ lé olómìnirà tàbí láti sọ fún wọn láti bẹ̀ ọ́ wò ṣùgbọ́n àlejò kan le bẹ̀ ọ́ wò. Tí àlejò àtìmọ́ lé olómìnirà bá bẹ̀ ọ́ wò nígbàtí o wà ní àtìmọ́ lé wọ́n yóò máa ṣiṣẹ́ láì ṣe pẹ̀ lú ọlọ́pàá láti ṣàyẹ̀wò bóyá a dáa ààbò bo ìlera àti àwọn ẹ̀ tọ́ rẹ. Ṣùgbọ́n, o kò ní láti bá wọ́n sọ̀ rọ̀ tí o kò bá fẹ́ sọ̀ rọ̀ .

Bí o ti le fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ hàn

Tí o bá fẹ́ fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ hàn bí a ti ń ṣe sí ọ, bèrè láti bá ọ̀gá ọlọ́pàá sọ̀ rọ̀ tó jẹ́ ọ̀ tẹlẹ̀múyẹ́ tàbí ipò tó gà jùlọ. Lẹ́yìn tí a ti fi ọ́ sílẹ̀ , o tún le fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ hàn ní èyíkéyìí àgọ́ ọlọ́pàá, sí Ilé-iṣẹ́ Olómìnira fún Ìhùwàsí Ọlọ́pàá (IOPC) tàbí nípasẹ̀ agbẹjọ́ rò kan tàbí MP rẹ lórúkọ rẹ.